Tókán ọmọ Àbádá
Inúmidùn Squad, ọ̀gá wa Dende
Ọmọ Egúngúngbohùn yìí o ṣé
Ọkọ Lará baby, Bàbá Akeem mi
Ọlá bàbá Junior, Bàbá Toheeb mi
Tókán ní n kí ẹ, ọmọ Àbádá
Àdúà lẹ fi ṣe fun, ó ti mú owó wá
Ẹ fi ara balẹ̀, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ màá gbówó yẹn sọ́hùn-ún
Àyìndé mọ́gbọ́láhàn arábámbí
Egúngún eégúngbohùn
Ó yá o Dende mi (Dende mi)
Ọ̀jẹ̀ ló l’òkétè (Dende mi)
Taofeeka gbogbo ara ní mo fi kí ẹ o Alhaja Taofeeka
Lójú agbo báyìí, ń ṣe la máa ń gbe wọnú ara wọn Àyìndé arábámbí
Yeh! Ọmọ Àbádá tó gbọ́n
Ẹ bá mi tọ́jú Dende ọkọ Lará ọmọ eégúngbohùn mi o
Ọlá bàbá Toheeb, owó bàbá Junior
Ọkọ Lará baby mi bàbá t’Akeem mi
Ẹ máa ṣe fàájì lọ
Arábámbí (arábámbí)
Bí èèyàn bá rí ọlọ́rọ̀ ẹni sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ ló ń dà
Gbogbo inúmidùn Squad, ẹ kú àdúrótì Murphy Ìjẹ̀bú ní kí n dúpẹ́
Òun ni bàbá ọmọ tó ń ṣe ìyàwó lénìí, Alhaji Wasiu arábámbí
Egúngúngbohùn Dende mi (Dende mi)
Ọ̀gá wa Dende mi (Dende mi)
Ọ̀jẹ̀ ló l’òkétè (Dende mi)
Ọ̀jẹ̀ ló l’òkétè (Dende mi)
Ṣ’àmín a ò ní fi ẹ́ ṣe àwátì (Dende mi)
Gbogbo wa pátápátá, a ò ní fi ẹ ṣe àwátì (Dende mi)
Àdúrà ẹ tó ń gbà, tí gbogbo wa tó ń gbà
Ń ṣe ló jọ bá ara wọn mu Àyìndé Arábámbí
Gbogbo ẹ̀ ń p’ọwọ́ ké ara wọn ni
Èèyàn ò ní wà, kó ná ní àwọn èèyàn ti ẹ̀
Àwa lèèyàn tì ẹ, ìwọ lèèyàn ti a
Egúngúngbohùn Dende mi ọkọ Sweet Lará
Ọ̀gá pátápátá IBD
Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì wa, Dende ó da ká lẹ́ni lẹ́yìn
Ẹni bá lẹ́ni lẹ́yìn ohun gbogbo ló ní
Gbogbo inúmidùn squad, àṣírí ẹ̀kọ wa kò ní tú lójú ewé
Ìkan ò ní ṣe ẹrú ara wọn nínú gbogbo wa
Gbogbo wa pátápátá, gbogbo owó tí a bá rán ńṣẹ́ yí ó padà wá sílé tèrètèrè
Irú èyí ta ń ṣe lénìí, a ó ṣe irú ẹ̀ fún ọmọ gbogbo wa ni
A ṣe irú ẹ̀ fún ọmọ SLAB ó ti ṣé
A ṣe irú ẹ̀ fún ọmọ dúdú, gbogbo wa la ó ṣe irú ẹ̀ fún ọmọ wa
Koboko, wàá ṣe irú fún ọmọ Àmín o
Taofeekatu mi Àlàkẹ́ adé
Dende ọmọ Egúngúngbohùn mi ò. Gbogbo ìgbà tí ayé bá ń jẹ́ ayé, tí ìgbà bá ń jẹ́ ìgbà, o ò ní ṣi ìgbà lo lọ́lá Ọlọhun Ọba
Ọ̀tá ẹ, ọ̀tá wa ni
Owó Dende, Ṣèyí ìdí ìrókò, ó l’ówó Dende lòun mú wá
Ṣèyí àyà, ó l’ówó Dende lòun mú wá
Ìdòwú owó ìyá, ó l’ówó Dende lòun mú wá
Martins Dodo Pẹ̀lú Túndé kanlé, wọ́n l’ówó Dende làwọn mú wá
Dúdú, ọba àwọn àjèjì, wọ́n l’ówó Dende làwọn mú wá
Al-Akeem, òyìnbó elépo akọ̀wé wa, ó lówó Dende lòun mú wa
Gbogbo yín, ah ah Obìnrin inú wa
East Koboko àti obìnrin inú wa, owó Dende ni wọ́n mú wá
Àlàkẹ́ adé tún f’Ọba le Taofeekatu mi, ó lówó De..
Akumari Bournvita
Ẹ farabalẹ̀, ó ti tó bí ọjọ́ mẹ́ta èèyàn kan ni mí ò rí níbí
Mò dẹ̀ ń béèrè ẹ
Kòsí ẹni tó sọ fún mi ibi tó wà o
Tani ẹni tí mò ń sọ Wasiu Ayinde
Adé Majek, mi ò rí ó tó ijọ́ mẹ́ta Wasiu Àyìndé
Òun náà ó m’ówó Dende wá
Engineer Kàmọ́rù, ó ti m’ówó Déńdè wá
Owó Dende gbogbo wọn mú wá
Paul Ipobe, ọmọ ti Fágbohùn bàbá wa ọmọ Ọbasanjo
Paul gbogbo Ipobe, ko bámi tọ́jù bàbá mi Ọbásanjọ́
Ọbasanjọ́ mi Bàbá ńkọ́
SLAB, owó Dende mi (owó Dende mi)
Àjẹmọ́nú Wese (arábámbí)
Sunne Ìbàdàn, aláṣẹ Julansky ó m’ówó Dende wa (owó Dende wa)
Engineer Lukman, ó m’ówó Dende wa (ó m’ówó Dende wá)
Owó Sokopa
Ẹ ṣé owó Dende wá (owó Dende wá)