Ijó wá dijó leader gbogbo
Latest Leader gbogbo Lagos State
Abdullahi Ẹnílọlóbọ̀ àti àwọn leader tó kù pátápátá
Usamat máa wolẹ̀ máa ràba
Shehu, o ṣeun mi
Ṣé ò ń bá mi tọ́jú Usamat Honourable Commissioner for Social Development and Youth
Gbogbo yín ni mo kí pátápátá
Alimosho Area ìkan ṣoṣo ni, lẹ fi kó gbogbo ilé pọ̀, ló fi dìkan
Kò ní bàjẹ́ lọ́lá Ọlọ́hun Ọba
Fẹ́mi, member Federal House of Representative ọmọ Adébájọ
Honourable Bísí ọmọ Yusufu mi o member, Lagos State House of Assembly
Àti Abudulahi ọmọ t’ẹní lọ ló bọ̀ ọkọ Shukurah, ọkọ Abibat mi
Woman leader ẹgbẹ́ wa máa wolẹ̀ máa ràba
Chief Mrs Kẹ́mi Nelson, o kú oríire, ọ̀rọ̀ social insurance ó jẹ wá lógún
Ìyẹn wá ń bẹ lọ́wọ́ wa báyìí, Buhari ti fún wa láṣẹ ko ma pàṣẹ lọ
Ọlọ́hun á fun yín ṣe ò, ọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà o
Àwọn gbẹ̀yìnbẹbọjẹ́, wọ́n ń bẹbọjẹ́ fún wa Wasiu Àyìndé
Latest Leader máa wolẹ̀ máa ràba Abudulahi mi
Alhaji Isah Yusufu mi o, latest leader
YY gbogbo ara ni mo fi kí ẹ o ọmọ Yusufu mi
Ọkọ Modúpẹ́ọlá mi ọkọ Modúpẹ́
Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì o
Alimosho Day, 2017
Gbogbo ẹ̀yin leader, mo ki yín o Àyìndé o
Woman leader nínú ẹgbẹ́ wa
Bólọ́hun bá ṣògo o, ó yẹ ká dúpẹ́
(Woman leader nínú ẹgbẹ́ wa)
(Bólọ́hun bá ṣògo o, ó yẹ ká dúpẹ́)
Chief Mrs Kẹ́mi Nelson, etí inú
Gbogbo ẹbí lékòó pátápátá
Lókè pòpó, ní ilé Tinubu ní Kakawa
Woman Leader Ẹgbẹ́ wa o, dé gbogbo South West
Chief Mrs Kẹ́mi Nelson mi
Ìyàwó Nelson mi Kẹ́mi baby mi
Chief Mrs, o mà kú oríire
Béèyàn bá gba Federal appointment Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn
9 yẹ ká ba jó
Woman leader nínú ẹgbẹ́ wa
Bólọ́hun bá ṣògo o, ó yẹ ká dúpẹ́
(Woman leader nínú ẹgbẹ́ wa)
(Bólọ́hun bá ṣògo o, ó yẹ ká dúpẹ́)
Ẹ̀dá tí ò bá dúpẹ́ oore Ọlọ́run Ọba o
Ó dàbí abara móore jẹ ni o
Bẹ́ẹ bá fun ni ohun tó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀
Kò ní dúpẹ́ Ọmọ́gbọ́láhàn ó yẹ ká dúpẹ́ Oore
Bó ti lè wù kó mọ bíntín
Oore Ọlọ́hun Ọba ni
Lágbára Ọlọ́hun Ọba lásìkò tì ẹ ó máa ṣe àṣeyọrí
O ti ṣe tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí
Àyìndé ní Lagos State, ṣé ẹ ní etí
Ó ti ṣe plenty plenty rí ní Lagos State
Chief Mrs Nelson, opportunity kan rè é fún gbogbo Nàìjíríà
Ẹ jẹ́ kí Abudulahi, ẹ jẹ́ ó dílé mú
Á máa lọ á máa bọ̀, ẹ jẹ́ ó ìdílé mú
Ló fi jẹ́ Apex, tí wọ́n bá p’èèyàn ní Apex Leader
Ilé lọ́wọ́ ẹ ló wà, Abdullahi ló ìdílé mú
Chief Mrs Kẹ́mi Nelson, Buhari ti fún ẹ láṣẹ o ò ri bí
Ọ̀rọ̀ Social Insurance NÍ gbogbo Nàìjíríà
K’áwa náà ká lọ ṣe tiwa níbẹ̀, ká le ṣe àṣeyọrí
Kẹ́mi Ọlọ́hun á bá ẹ (Ọlọ́hun á bá ẹ ṣé)
Eh!
Woman leader gbogbo South West
Oyè púpọ̀ ló kó dání, ó kó South West ó ko dání
Ó mú Lagos State, ó ko dání
Ó tún mú Federal, ó tún mu dání
Gbogbo ẹ̀ gbògbò ẹ̀ lọ́wọ́ Àkànbí ọmọ Olódó idẹ o
Kú lé mi ò tún gbọ́dọ̀ pè ẹ́ mọ́
Adúpẹ́ lọ́wọ́ leader Aṣíwájú
Ibi téèyàn bá ṣe sí ló ti ń jẹ Àyìndé mi Gbọ́láhàn o
Nígbà téèyàn ń ṣe ọmọ ẹgbẹ́, Chief Mrs Kẹ́mi Kẹ́mi
O ṣe ohun ẹgbẹ́ gidi
Ìgbà tó tún di leader, tó tún jẹ́ olórí
O tún ilé ṣe, tún ọ̀nà ṣe, o tọ́jú ará
Kẹ́mi Nelson, o tọ́jù ẹbí
Adúpẹ́ fún Ọlọ́hun Ọba, èyí ò tíì tó
Bó bá jẹ Minister nílẹ̀ yìí kò mà pọ̀ àpọ̀ jù
Ṣùgbọ́n, ẹsẹ̀ kan là á gbé kátó gbé ìkan ò Àyìndé mi Gbọ́láhàn o