ba Oníàá (Live)-文本歌词

ba Oníàá (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Àyánkúnlé pẹ̀lú Perry o

(Wọ́n ti nawọ ya, wọ́n na’wọ dẹ̀, wọ́n ti na’wọ ya)

Èédú àti ètùtù, Olúberí àti Àyánkúnlé o

(Wọ́n ti na’wọ ya, wọ́n na’wọ dẹ̀, wọ́n ti na’wọ ya)

Jésù mi o

Olúbẹrí o, (wọ́n ti na’wọ ya, wọ́n na’wọ dẹ̀, wọ́n ti na’wọ ya)

Ọmọ Naija ta bá ní sùúrù (ohun tó lọ á bọ̀ o)

Ohun tí ò tó mo ló máa ṣẹ́kù (gbogbo wa á fojú rí)

Ẹ̀yin Ọba ládé ládé, kábíyèsí ẹ máa wolẹ̀, ẹ máa rọra

Ọba Asimiyu mi bàbá mi

Elégbè of Ègbè, Àtàndá adé mi bàbá mi

Kábíyèsí, kábíyèsí mi arọ́bafín lọba ń pa

Ọkọ olorì Shifau ọkọ Adétutù mi Ọba ni

A kú oríire t’ọdún Èní, Alimosho Day

Ọdọọdún là ń r’órógbó, àwa ta ṣe ọdún tó kọjá lọ o

A tún péjú síbí, kábíyèsí Elégbè tó legbè o

At’Ọba Babátúndé Nasirullahi mi Lawal mi

Àkànbí, Ògúnróunbí mi Àkànbí o

Àmín lọ́wọ́ mi àkọ́kọ́,

Ọba Oníṣàṣá ilé lọ́wọ́ ẹ ló wà, ẹ ẹ̀ ri

Ọkọ Fúnmiláyọ̀ mi Jùmọ̀kẹ́

Ọkọ Rasheedatu mi Ọláyínká ayaba

Òòṣà bàbá Òòṣà bàbá ọmọ méjì mi

Mo ki yín, ẹ kú ọdún Alimosho Day

Àtẹ̀yin àti Ọba Asimiyu mi bàbá mi, Àtàndá

Dada Ọba gbogbo ara ni mo fi kí ẹ Àtàndá Adé

Àtàndá, Elégbè tó legbè o

Kí ẹ bá mi kí Ọba Azeez Gbagadiyu aṣíwájú àti Kábíèsí Sulemona mi Suberu mi

Ojú Àlàdé Alájàsa t’Àjàsá, ẹ̀yin Ọba ládé ládé mo ki yín

Ọba Samuel Awóyẹmí Àdìsá Ismaila òrójà onímẹran of Mẹran

Ọkọ Olorolì Halimot mi Afọláshadé

Chief Abdul Hakeem Ọláwálé Ògúnrẹ̀mí Olómitútù mi o ṣeun

ojú òyè gbogbo Mushin ọkọ Basira

Alimosho Day, àwa ta ṣe ọdún eléyìí, a ó ṣe tẹ̀míì si gbogbo wa

Arọ́bafín l’Ọba ń pa o Àtàndá Asimiyu mi

Oníṣàṣá,

Ẹyin ló ń d’akùkọ, O mà ṣé Ọlọ́hun Ọba

Ẹyin ló ń d’akùkọ, O mà ṣé Ọlọ́hun o

(Ẹyin ló ń d’akùkọ, O mà ṣé Ọlọ́hun Ọba)

(Ẹyin ló ń d’akùkọ, O mà ṣé Ọlọ́hun Ọba)

Ó di gẹ̀rẹ̀gẹ̀rẹ̀ ó di Bàbá

Ẹyin ló ń d’akùkọ, O mà ṣé Ọlọ́hun Ọba

Ẹyin ló ń d’akùkọ, O mà ṣé Ọlọ́hun o

(Ẹyin ló ń d’akùkọ, O mà ṣé Ọlọ́hun Ọba)

(Ẹyin ló ń d’akùkọ, O mà ṣé Ọlọ́hun Ọba)

Séríkí Hausa wa

Gbogbo Alimosho, Alhaji Ahmed Haruna

Séríkí gbogbo Hausa wa l’Alimosho area Séríkí Hausa wa

Alimosho Day 2017 a péjú ṣ’ọdún eléyìí Ọmọ́gbọ́láhàn

A ṣẹ̀míì si tọmọtọmọ, Séríkí Hausa wa

Alaikia (alaikia eh) go

Séríkí Hausa wá

Alaikia (Alaikia eh)

A laik’Imamu lafia (Alaikia eh)

Ahmed Haruna mi (Haruna mi)

Awo Alhaji Isah Liasu (Haruna mi)

Séríkí ń ṣàṣá, awo Isah Liasu (Haruna mi)

Awo Sunny, Sunny Muhammad (Haruna mi)

Awo Alhaji Samba (Haruna mi)

Alhaji Samba (Haruna mi)

Alhaji Samba (Haruna mi)

Séríkí ń ṣàṣá (Séríkí ń ṣàṣá)

Isah Liasu (Séríkí ń ṣàṣá)

Isah Liasu (Séríkí ń ṣàṣá)

Alaikia (Alaikia eh)

Kábíyèsí, àsìkò òṣèlú mà ti bẹ̀rẹ̀ (Alaikia eh)

Àsìkò òṣèlú mà ti bẹ̀rẹ̀ (Alaikia eh)

Àsìkò òṣèlú mà ti bẹ̀rẹ̀ (Alaikia eh)

Ní Lagos State, a máa ṣe local government election (alaikia eh)

Gbogbo ìbò ṣá lafẹ́ gbà (Alaikia eh)

Gbogbo ìbò ṣá lafẹ́ gbà (Alaikia eh)

Ọlọ́hun á báwa ṣe (Ọlọ́hun á báwa ṣe)

Séríkí ń ṣàṣá (Séríkí ń ṣàṣá)

Àsìkò òṣèlú mà ti bẹ̀rẹ̀ (Séríkí ṣàṣá)

Ní Lagos State, a máa ṣe local government election (Ọlọ́hun á báwa ṣe)

Gbogbo local government, ẹ̀yin t’Alimosho ṣé ẹ ti múra sílẹ̀

(Ọlọ́hun á báwa ṣe)

Gbogbo Council Alimosho, ṣé gbogbo wa la ti múra sílẹ̀

(Ọlọ́hun á báwa ṣe)

Gbogbo ẹ̀yin leader leader leader leader

Ẹ̀yin òṣèlú l’Alimosho Ọlọ́hun á bá wa ṣé

Alimosho Parapọ̀, ṣé ẹ ti múra sílẹ̀ (Ọlọ́hun á báwa ṣe)

Àwọn Àdìmúlà, ṣé gbogbo ilé ti múra sílẹ̀ (Ọlọ́hun á báwa ṣe)