m oní’f (Live)-文本歌词

m oní’f (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Doyin ọmọ Adémilúyì mi (doyin ọmọ Adémilúyì mi o)

Doyin ọmọ Adémilúyì mi (doyin ọmọ Adémilúyì mi o)

Ọmọ oní'fẹ̀ abùrẹ́ o ṣeun o

Ọmọ oní'fẹ̀ abùrẹ́, adádé owó rẹmọ

Ọmọ oní'fẹ̀ abùrẹ́, adádé owó rẹmọ

Doyin ọmọ Adémilúyì wàá d’ ádé owó rẹmọ

(Ọmọ oní'fẹ̀ abùrẹ́, adádé owó rẹmọ)

(Doyin ọmọ Adémilúyì ọmọ adé owó rẹmọ)

Etí inú

Doyin ọmọ Adémilúyì, etí inú

Tí n bá ń ba yín wí ẹ má ṣ’ agídí

Doyin ọmọ Adémilúyì, Ifẹ̀ oòyè

Ọmọ oní'fẹ̀ ọọ̀ni Adémilúyì ọmọ onífẹ̀ ọọ̀ni

Ọmọ Adémilúyì nífẹ̀

Ifẹ̀ oòyè, a kìí dúró kí wọn ní’ fẹ̀

A kìí bẹ̀rẹ̀ kí wọn ni’ fẹ̀ oòyèlàgbò

Ẹni bá dúró kí wọn ní’ fẹ̀ gúnnugún ẹbọ ni wọ́n ń firú wọn ṣe o

Ni wọ́n ń fi ú wọn ṣe

Ọmọ Adémilúyì, doyin oní'fẹ̀ ọọ̀ni

Ifẹ̀, ìlú kábíyèsí Ògúnwùsì kábíyèsí oní'fẹ̀ ọọ̀ni

Ẹni ìtàn Ọba ni, Ọba Ọọ̀nirìṣà mi ńkọ́

Ọ̀jájá mi ní’ fẹ̀, Kábíyèsí Ọ̀jájá

Ìyẹn náà ṣe ọjọ́ ìbí, kábíyèsí many happy returns

Ọ̀jájá lórí Ọba

Doyin Adémilúyì, awo tèmi Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn arábámbí

Doyin baby

Ọmọ oní'fẹ̀ abùrẹ́ (Ọmọ oní'fẹ̀ abùrẹ́)

Ah! Ifẹ̀ nílé Odúdúwà (Ọmọ oní'fẹ̀ abùrẹ́)

Èrò ká relé Ifẹ̀, doyin Baby

Èrò ká relé Ifẹ̀ Eh eh

(Ayé ọ̀jà ifẹ̀ èrò ká relé ìfẹ̀)