Late Chief Samuel (Live)-文本歌词

Late Chief Samuel (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Ojú ẹni ma là á rí tó (ojú ẹni ma là á rí’yọnu)

Nigeria la ti bẹ̀rẹ̀ eré, everybody ló ń bá’wa jo

Torí má fara kàn mí kìí lọ s’ọ́jà lọ ra nǹkan iba Saida

Aya t’Ológbùró, máa wolẹ̀ máa rọra o

Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì ẹbí Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn

Alhaja Bọ́lá aya Ọ̀yọ́ Aláàfin, òjò pa Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ọmọ àtìbà ma ì

Ológbùró ńkọ́ o ‘Bátúndé?

Gbogbo ẹ̀yin èèyàn tó ń bẹ níkàlẹ̀

Gbogbo wa la máa gbẹ̀yìn arúgbó wa sí dáadáa o

Ẹ kú àdúrótì gbogbo ẹbí Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn

Wọ́n dúpẹ́ Ọmọ́gbọ́láhàn, wọ́n ní ẹ ṣeun

Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń wí, mo recognise presence, distinguished Senator ọkọ Folasade

Ẹ kú àdúrótì wa o, Bariyu ọmọ t’Ashafa

Ọmọ oníbẹ̀jù agbè

Bàbá gbogbo àwọn boys

Téèyàn bá ní aṣíwájú dáadáa o, t’ó bá l’áṣíwájú rere

Ò ọgbọ́n ṣe é, ó ń fi ọmọ ènìyàn ṣè é

Ó fi sùúrù ìwàpẹ̀lẹ́, oríadẹ́tù

Ó fi kó gbogbo ọmọdé jẹ̀ pẹ́, wàá kó wa jẹ̀ pẹ́ Ọmọ́gbọ́láhàn lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba

Ashafa mi Bariyu, ikú ò ní pa ẹ́ fún mi Ashafa o

Kọ́lé ọmọ Ọlátúnjí, Iman, owó ọkọ Gbémisọ́lá

Ẹ kú àdúrótì, gbogbo ẹbí Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn, wọ́n ń dúpẹ́ dúpẹ́

Dòdóńdáwà, ọmọ Balógun o

Ishoye ní’jẹ̀bú ọkọ Àdùnní mi Risikatu Afọláshadé

Ẹ kú àdúrótì gbogbo ẹbí Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn, wọ́n ń dúpẹ́

Àlàké Adé OFLAK

Mo kí ẹ, kí ẹ Àlàkẹ́, ẹ kú àdúrótì ẹbí Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn

Nikky, Shadia, gbogbo yín ni mo kí, Ìyá àti Àlàkẹ́ Adé Taofeekah

Taofeekatu ní’bàdàn Àlàkẹ́ adé

Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì ẹbí Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn

Àdùnní mi má a wolẹ̀, Àdùnní Mọ̀rúfátù

Adétóún, Alhaja Sẹ̀kí, gbogbo yín ẹ kú àdúrótì, mo ki yín

Ọláitán ọmọ Morufatu, aya Akilẹ̀ Adémọ́lá àti Àkànbí Akumari ọmọ Adéṣọpẹ́, owó ọkọ ‘détóún

Ẹ kú àdúrótì, mo ki yín

Ọláídé, mo kíi yín, ẹ kú àdúrótì gbogbo yín ẹ ṣé

Ẹbí Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn wọ́n ń dúpẹ́

Gbogbo ẹ̀yin èrò lọ́tùn-ún ẹ̀yin èèyàn gidi lósì

Èèyàn pàtàkì láàrín ìlú, gbogbo wa lèèyàn pàtàkì

Torí b’éèyàn bá l’ẹ́ni lẹ́yìn, bí Ọba ló rí

Gbogbo Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn ń dúpẹ́ Ọmọ́gbọ́láhàn, wọ́n ní ẹ ṣeun ṣeun

Èní kà ń ṣe’lédè bàbá wa Late Chief Samuel Taiwo Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn

A dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́

To rí máfarakànmí kìí lọ s’ódò lọ ra nǹkan Iba Saida

Ó di téré nà nà nà jáláńká to

(Téré nà nà jáláńká to)

Ó di téré nà nà nà jáláń ká to

(Téré nà nà jáláńká to)

Ẹni jára mọ́’ṣẹ́ (jáláńká to)

Irú wọn kì í jẹ̀bi (jáláńká to)

Èrè ni wọ́n ń jẹ bọ̀ ọjà o (jáláńká to)

Téré nà nà nà jáláńká to

(Téré nà nà jáláńká to)

Téré nà nà jáláń ká to

(Téré nà nà jáláńká to)

Téré nà nà jáláń ká to

(Téré nà nà nà jáláńká tó)