Ibrahim lọ jókòó ọmọ Wasiu ni ẹ́
O ò sí nínú K1 Band
O lówó lọ́wọ́, ó tún fẹ́ ṣá mi jẹ
Ọ̀rọ̀ àwa ẹ̀dá láyé
B’ógún bá jẹ lọ Ọgbọ̀n á jẹ padà
Ògé dé o Ọba ẹyẹ
Àyìndé dé o Ọba orin
Ẹ wọlé ire ẹ f’ògé sí o
Ìyá ọmọ o
Ìyá ọmọ kìlọ̀ f’ọ́mọdé ẹ ò ó ń fikú ṣeré
Igi ìbẹ́pẹ tí ò lẹ́sẹ̀ ló mí gùn o
Ohun gbogbo lọ́wọ́ orí
Ẹni orí bá ti dá, orí ti dá yẹn ná
Ó wá ń dára báyìí o o
Mo wá bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun Ọba
Má fi kíkan sọ́rọ̀ gbogbo wa
Ká má jẹ egungun gbẹ̀yìn ẹran
Ọ̀rọ̀ tí mò ń wí, àpò ṣáṣamùrá oh eh
Àpò tẹ ń tọwọ́ bọ̀ tí gbogbo yín ti ń mówó lójoojúmọ́
Ṣáṣamùrá, jí’ọ́n mọ̀ dà? Ṣáṣamùrá
Ìyá ọmọ o
Ìyá ọmọ kìlọ̀ f’ọ́mọdé ẹ ò ó ń fikú ṣeré
Igi ìbẹ́pẹ tí ò lẹ́sẹ̀ ló mí gùn o
Bàtà sómi wẹ́rẹ́ wẹ́rẹ́
Bàtà sómi wẹ̀rẹ̀ wẹ̀rẹ̀ só batá
Bàtà bla bla bàtá, Bàta bla bla batà
Awúyẹ́ wuyẹ̀ wuyẹ A blata blata baba
Ewúrẹ́ ilé mi Salamọ́tù
Àgùntàn ilé ẹ Salamo yeh!
Àdùkẹ́ làwa ń bá ṣeré olówó ẹyọ
Àdùkẹ́ làwa ń bá tayò olówó ẹyọ
Ìyá ọmọ o
Ìyá ọmọ kìlọ̀ f’ọ́mọdé ẹ ò ó ń fikú ṣeré
Igi ìbẹ́pẹ tí ò lẹ́sẹ̀ ló mí gùn o
Ẹ bá mi pé á mà ṣẹ ò àṣẹ
Ẹ bá mi pé á mà ṣẹ ò àṣẹ
Ọdún ló dé (àṣẹ)
Ba ṣe ń ṣe lọ́dọọdún (àṣẹ)
(Àṣẹ)
Ọdún ló dé (àṣẹ)
À ń jó, À ń yọ̀ ni o (àṣẹ)
Ẹ bá mi pé á mà ṣẹ o (àṣẹ)
Ọmọ wa ò ní kú (àṣẹ)
Àwa gangan ò ní kú (àṣẹ)
Ẹ bá mi pé á mà ṣẹ o (àṣẹ)
Iré dé, iré dé o
Iré dé, iré dé o
2nd of January mọ́jú 3rd
Àyìndé mi Wasiu pẹ̀lú Hunter
Bá a ti ṣe ń ṣe lọ́dọọdún
Olúayé Fújì èrò kó wá
Wọ́n wá láti America wá láti London
Láti Canada gbogbo wọn jáde
Wọ́n wá jó, wọ́n mí a yọ̀
Ire wọlé dé, (ọdún ló dé la mí a yọ̀ o)
Gbogbo yín tí ẹ wálé láti ìlú òyìnbó
Àti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń bẹ nílùú Nàìjíríà níbí
Ẹ ò ní dọlárẹ̀yìn lọ́lá Ọlọ́hun
Àdúrà wa á máa gbà o (ire wọlé dé)
(Ọdún ló dé la mí a yọ̀ o)
Mo wá ń bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun Ọba Illahi tó layé
Má ì tíì fi ikú tó yá pa wá
Ká dàgbà ká darúgbó o Olúayé onífújì o
(ire wọlé dé, ọdún ló dé la mí a yọ̀ o)
Iré dé, iré dé o
Iré dé, iré dé o
Àyìndé mi Gbọ́láhàn
(Iré wọlé dé, ọdún ló dé la mí a yọ̀ o)
Olásúnkànmí mi Àyìndé adé o Ojúṣàágbọlá o ọ̀gọjì o
(Iré wọlé dé, ọdún ló dé la mí a yọ̀ o)
Hunter, wọn ò wá ní f’ọmọ ẹlòmíì kí wọ́n fi ṣe ẹ́
Ìwọ l’America, ìwọ ní London
Ìwọ ní Canada lójoojúmọ́
Ọjà ẹ tó ti lérè kò ní fọ́ ká mọ́ ẹ lọ́wọ́ o
Lọ́lá Alawura o
(Iré wọlé dé, ọdún ló dé ká mí a yọ̀ o)
Iré dé, iré dé o
Àyìndé ẹ mí a yọ̀ o
(Iré wọlé dé, ọdún ló dé ká mí a yọ̀ o)
Ọba tó lòkun lọ̀sàò ò mà ní jẹ́ a tẹ́ o
Alawurabi á tìwá lẹ́yìn o
(Iré wọlé dé, ọdún ló dé ká mí a yọ̀ o)
Ọ̀gbẹ́ni ọjà, Murphy Adékọ̀yà ò gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Ọ̀gbẹ́ni ọjà gbogbo ìlú àgọ́ o
O ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn o
(Iré wọlé dé, ọdún ló dé ká mí a yọ̀ o)
Taiwo Kehinde o ò gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Àyìndé ẹ mí a yọ̀ o
(Iré wọlé dé, ọdún ló dé ká mí a yọ̀ o)
O ò gbọ́ bí mo ṣe ń sọ ni Àdufẹ́ adé mi
Ọdún ló dé kẹ mí a yọ̀
(Iré wọlé dé, ọmọ mi Àdufẹ́ Tèmidayọ̀ o)
Iré dé, iré dé o Àdufẹ́ Tèmidayọ̀
(Iré wọlé dé, Àdufẹ́ Tèmidayọ̀ o)
Ẹ jẹ́ mi ní ehn kí n gbọ́ (ehn)
Ẹ ẹ̀ jẹ́ mi ní ehn kí n gbọ́ (ehn)
Jẹ́ mi ní ehn kí n gbọ́ (ehn)
Àyìndé ewé ayò (ehn) Ewé òtún méje (ehn)
Itún ló ní kí wọ́n tún wa ṣe (ehn)
Ìfà ló ní kí wọ́n fà wá mọ́ra (ehn)
A kìí bínú k’ogún ataare (ehn)
Mo gún méjì ọkà bàbà (ehn)
Mo gún mẹ́ta ọkà wáṣẹ (ehn)
Orí ló túmọ̀ ẹnu (ehn)
Gbòǹgbò ọ̀nà ló ń túmọ̀ ẹsẹ̀ (ehn)
Ìmọ̀ tú ìmọ̀ jọ (ehn)
Ìmọ̀ èmi ni wọn kìí dalẹ́ (ehn)
Bí wọ́n bá lọ mú ẹlẹmọ́ (ehn)
Wọ́n á fi jẹ oyè Ẹlẹmọ́ (ehn)
Bí wọ́n bá lọ mú efìrì (ehn)
Wọ́n á fi joyè erùkú (ehn)
B’ọ̀wọ́ wọn bá tẹ̀’gbín (ehn)
Wọ́n á fi joyè Aláré (ehn)
Àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta parapọ̀ (ehn)
Wọ́n wá jọ ń p’ẹmọ́ (ehn)
Ẹmọ̀ ò lóko jẹ (ehn)
Wọ́n ń p’Akíntọ́lá (ehn)
Akíntọ́lá ọmọ Ògún (ehn)
Wọ́n ń p’Ajíyọdà (ehn)
Ọmọ Àkàràmọgbà (ehn)
Wọ́n ń p’Ajíṣàdádadẹ (ehn)
Ọmọ Ọba Ìjẹ̀bú mère (ehn)
Ó dògbólùkẹ̀rẹ̀ (ehn)
Ajagun ló l’òde ọ̀run (ehn)
Èjìrẹ́ bó bá ṣe pé tẹ̀yin (ehn)
Tí wọ́n bá ń dárí jọ wí (ehn)
Àgbéró nikú ń gbọ́wọ́ (ehn)
Ọ̀gọ̀ tí ṣìgìdì bá gbé (ehn)
Àgbétì ló máa ń gbe (ehn)
Àyantì là ń yan ewúrẹ́
Kọ́lọ́hun dákun má padà lẹ́yìn gbogbo wa
(Kó má gbàgbé ọ̀rọ̀ t’a jọ sọ)
Polanco, Ọlọ́hun dákun má padà lẹ́yìn gbogbo wa
(Kó má gbàgbé ọ̀rọ̀ t’a jọ sọ)
Ọlọ́hun dákun má padà lẹ́yìn gbogbo wa
(Kó má gbàgbé ọ̀rọ̀ t’a jọ sọ)
Ọlọ́hun dákun má padà lẹ́yìn gbogbo wa
(Kó má gbàgbé ọ̀rọ̀ t’a jọ sọ)
Ọlọ́hun dákun má padà lẹ́yìn gbogbo wa
(Kó má gbàgbé ọ̀rọ̀ t’a jọ sọ)
Àyìndé mo tún dé o (agbólóhùn bí ọ̀jẹ̀ o)
Agbólóhùn bí ọ̀jẹ̀ nínú eléré
Àyìndé o agbólóhùn bí ọ̀jẹ̀ ( nínú eléré)
(Nínú eléré mọ́gbọ́láhàn Aláyìndé ló d’Ọba oh eh)
Ẹlẹlẹ Mesiko ọkọ Mosúnmọ́lá
(Ẹlẹlẹ Mesiko ọkọ Mosúnmọ́lá)
Ẹlẹlẹ Mesiko ọkọ Mosúnmọ́lá
(Ẹlẹlẹ Mesiko ọkọ Mosúnmọ́lá)
Olúayé Fújì (Ọ̀gá wa o)