p tì  (Live)-文本歌词

p tì (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Àgbẹ̀dẹ Taju mi (taju mi)

Mo f’ọlọ́hun búra (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Èèyàn Tó bá ní ẹ lẹ́yìn (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Ọlọ́hun ṣá ni wọ́n bá tò o (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Èèyàn Tó bá sọ ẹ́ nù (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Ń ṣe ló sọ Ọlọ́hun nù (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Tòótọ́, a ò fi ẹ́ wé Ọlọ́hun o (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Ṣùgbọ́n ò ń tún iṣẹ́ Elédùmarè ṣe (àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Ò ń tún iṣẹ́ Elédùmarè ṣe (Àgbẹ̀dẹ Tajú mi)

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ òun lo fi ń jẹ leader (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Lo fi ń dá ni lọ́rùn (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Epo kín kín, òun ló ní n kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Odùsànyà ní n kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Kunle Poly ó ní n kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Jay Paul ni ń kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Siro, kò wá bí?

Ó ní n kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Àti Àyìndé mi Musiliu (Ayédáadé)

Ọmọ mi Àyìndé adé mi o(Ayédáadé)

Gbogbo wa ní n kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Pẹ̀lú sitapha (pẹ̀lú musitapha)

Abiamọ ni ẹ́ Taju, gbogbo wọn ló ní n kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Ìwọ ni alábínú a máa a, alábínú a máa sá sí

Alábínú a máa (alábínú a máa sá sí)

Pẹ̀lú kúdẹrẹ́tì, gbogbo wọn ló ní n kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Pẹ̀lú Kúdẹrẹ́tì gbogbo wọn ní n kí ẹ (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Gbogbo Chief Lagos ni wọ́n ní n kí ẹ o (Àgbẹ̀dẹ Taju mi)

Èmi Àyìndé ni leader (Arábámbí)

Bàbá gbogbo ilé, Ṣọpẹ́

Bí èèyàn bá ti gùn’kè àgbà

Ó ti di abiamọ, abiamọ alábínú a máa sá sí

Ìyẹn ni wọ́n ń pè ní abiamọ, abiamọ b’ọ̀já gbọ̀rọ̀ gbọrọ alábínú a máa sá si

Ṣọpẹ́, b’éèyàn bá ní sùúrù ohun gbogbo ló ní

Ẹni bá ṣe aṣíwájú, onísùúrù ló ń jẹ aṣíwájú

Àwọn ni wọ́n ń jẹ́ onínúure

Ọjà ìwọ̀sí òun ṣá ni wọ́n ń pè ní leader arábámbí

Taju mi (Taju mi)

Bó o bá wá jayé títí, gbogbo ara tì ẹ

Mo kí Alhaji Mohammed Najimu ọmọ Yasin

Ìyẹ̀rú ọ̀kín ọmọ Ọlọ́fàmọjọ̀ ọmọ abíṣujóókọ

Yasin ko máa bá mi ki, Alhaji Nojimu ọmọ Yasin

Gbogbo ara tì ẹ, o yà ní ẹ̀gbá ilé ogun State

Ko bá mi kí Jango, Brother tèmi Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn arábámbí

Ibẹ̀ ni mo fi yà, ó di ìlú Ìbàdàn

Ó jẹ State, ó jẹ Zonal Chairman inúfẹ́lẹ́ t’ebi kọ́

Àgbà tí ò yọkùn ahun ló ní

Ó Fẹ́lẹ́ lẹ́nu ọmọ t’Òyérìndé, ó tutù d’ọ́kàn inúfẹ́lẹ́

Brother tèmi Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn arábámbí

Ah!

Ẹ̀yin tèmi bẹ bá ní sùúrù ó ṣì máa dára lọ́lá Ọlọ́hun

Taju, gbèjò gbèjò tó bá ní sùúrù (Á kún garawa lọ́jọ́ ọjọ́ kan àfàìrọ̀ òjò)

Gbèjò gbèjò tó bá ní sùúrù (Á kún garawa lọ́jọ́ ọjọ́ kan àfàìrọ̀ òjò)

Gbogbo gbèjò gbèjò tó bá ní sùúrù (Á kún garawa lọ́jọ́ ọjọ́ kan àfàìrọ̀ òjò)

Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ

(Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ)

Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ

(Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ)

Bàbá 70, ó wá náwó leader

Ó náwó Taju ọmọ Àgbẹ̀dẹ

Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ

(Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ)

Taju ló ìdílé mú (Àgbẹ̀dẹ Taju ló dílé mú)

Mo ṣì ń bọ̀ lórí Afeez Nínálowó

Mò ń bọ̀ wá o Wasiu àlàyé ń jó lọ́wọ́

Lẹ́ẹ̀kan si Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ

(Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ, Ṣọpẹ́ tì ẹ)

Ọlọ́mọge skimpy skimpy, ìwọ là ń kí