À ń rí ẹ báyìí, a ò ní banújẹ́
Ìwọ náà ò ní sunkún lórí ọmọ
Òun ni Chief Security inú ẹgbẹ́
Chairman Security committee, Ògbójú
Ògbójú èèyàn ló ń jẹ olórí ọdẹ
Èèyàn Tó lẹ́nu lásán, èèyàn bíńtín
Èèyàn tí wọ́n lè fi ìka kan tì kìí jẹ olórí ọdẹ
Olórí Ọdẹ, the great hunter yìí o ṣé
Tó jẹ́ pé tó bá fẹ́ atẹ́gùn lásán, atẹ́gùn ẹ̀ eré ni
Àṣẹ ni, tó bá na ọwọ́ kan sókè lásán gbogbo ọmọ ọdẹ
Po po po po, The great hunter yìí o ṣé Tọ́lání
Ọmọ Adébáyọ̀ mi Tọ́lání
Mo kí ẹ kí ẹ ọmọ t’Ògúnlàdé o
Ọmọ Ògúnlàdé mi Bongo Tọ́lání
Awo Jewelries, awo Jewelries Tọ́lání
Ilé lọ́wọ́ ẹ ló wà Tolani
Gbogbo Alimosho
A ṣọdún èyí a ó ṣe ẹ̀ẹ́mì si tọmọ, àdúrà ẹ á máa gbà o
Èmi tìkalara
Ẹsẹ̀ mi òní sìn níbí, nílùú Alimosho
Lágbára Ọlọ́hun Ọba lórí tì ẹ ìlérí Olúwa ó máa ṣe
#INSTRUMENTAL
Kemo!
Organizing committee okay now
Gbogbo àwọn ọmọ dà?
Kó gbogbo àwọn ọmọ wọlé, ẹ ṣí wọn wọlé
Ẹ ṣí wọn wa
Aunty
Tọ́lání o ṣé (Tọ́lání o ṣé)
Gbogbo Alimosho ni n dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ (Tọ́lání o sẹ́)
Wọ́n lo lú àdúrótì
Ilé lọ́wọ́ ẹ lówá (Tọ́lání o sẹ́)
Ilé lọ́wọ́ ẹ lówá (Tọ́lání o sẹ́)
Ọmọ Ògúnlàdé (ọmọ Ògúnlàdé)
Ọmọ t’Ògúnlàdé mi Bongo (ọmọ Ògúnlàdé)
Ọmọ Ògúnlàdé mi Samson (ọmọ Ògúnlàdé)
Ògúnlàdé mi Bongo (ọmọ Ògúnlàdé)
Awo Jewelries, Ògúnlàdé mi Bongo (Ọmọ Ògúnlàdé)
Tọ́lání o ṣé (Tọ́lání o ṣé)
Tọ́lání o ṣé (Tọ́lání o ṣé)
Ẹ bá mi k’ọ́mọ Adédayọ̀ (Tọ́lání o ṣé)
Ẹ bá mi k’ọ́mọ Adédayọ̀ (Tọ́lání o ṣé)
Oracle mi (Oracle mi)
Oracle mi (Oracle mi)
Oracle mi (Oracle mi)
Oracle mi (Oracle mi)
Oracle mi (Oracle mi)
Ọmọ ni Tọ́lání o káre (Oracle mi)
Ọmọ t’Ògúnlàdé mi Bongo (Oracle mi)
Ọmọ Ògúnlàdé mi Bongo (Oracle mi)
Ọmọ Ògúnlàdé mi Bongo (Oracle mi)
Ọmọ Ògúnlàdé (ọmọ Ògúnlàdé)
Ògúnlàdé mi Bongo (Ọmọ Ògúnlàdé)
Ọmọ Ògúnlàdé mi Bongo (ọmọ Ògúnlàdé)
Ṣé ò ń bá mi tọ́jú Jewelries (ọmọ Ògúnlàdé)
Ṣètọ́jú Jewelries (àwọn ọmọ Ògúnlàdé)
Oracle mi (Oracle mi)
Oracle mi (Oracle mi)
Tọ́lání Adédayọ̀ ma gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Àwọn tí ò mọ̀’kan, wọ́n á ní Tọ́lání Danger
Àwọn Ọ̀dẹ̀ èèyàn, Tọ́lání serious
Ẹ kí serious mi Tọ́lání
Ògúnlàdé mi Bongo mi oracle mo kí ẹ
Ko bá mi tọ́jú Tọ́lání owó bàbá Yínká
Bàbá Samson yìí o káre
Bàbá t’Ìfẹ́olúwa o ò ri bí
Bàbá Faith, Bàbá ṣeun
Ọlọ́hun kó wo gbogbo wọn fún ẹ, kó dá ẹ sí
Ìwọ náà wà á jẹun ọmọ Àyìndé ‘mọ́gbọ́láhàn gbogbo wa ló máa yó
Àsùnmọ̀, b’éèyàn bá ní sùúrù á jogún ilé ayé
Yí ó tún jogún ọ̀run
Ibo gan lọ̀run wà ná?
Àwa ò r’ẹ́ni tó lọ síbẹ̀ tó dé rí
Kó wá ròyin ẹ̀ fún wa
Ṣùgbọ́n kinní kan tí mo mọ̀ tó dá mi lójú
Inú ayé lọ̀run wà o Àyìndé mi Wasiu
Èèyàn ò bá à kú ní twenty times Àyìndé
Inú ayé lọ̀run mà wà Arábámbí
Èmi ń jayé níjẹ̀bú òde Arábámbí
Ilé Ojúṣàágbọlá Ọ̀gọ́jì ni gbogbo nǹkan
Mò ń ṣe dede nẹ́ẹ̀
Anọbi ó ń jayé pẹ̀lú àwọn saabi ẹ̀
Nílé Ojúṣàágbọlá Ọ̀gọ́jì Arábámbí
Àyìndé níjẹ̀bú òde
Bí mo ṣe ń jẹ’tan ẹran, bó bá wù mí mo lè ní wọ̀n ó ṣe ẹran bi mẹ́fà arábámbí
Mà á ma ṣe bó ṣe wù mí nílé Ojúṣàágbọlá Ọ̀gọ́jì Àyìndé adé
Àwọn Henry wọ́n ń jẹun, wọ́n ń yó
Kí lórúkọ ìkejì ẹ̀?
Ó ní òun àti Ismaila, ó ní pali bí ọtí mẹ́fà làwọn kó wá sílé
Nígbà yẹn asunmo, Empire ló sọ bẹ́ẹ̀ Arábámbí
O ò sọ bẹ́ẹ̀? Ó ní ìwọ àti Asunmo
Ó ní ọtí bí i pali mẹ́fà làwọn kó wá sílé
Asunmo, ó ní ẹ dán ohun tó tó yẹn wò carton Ọdún mẹ́fà
Kìí ṣe beer, kìí ṣe wine
Brandy! Tó bá dijọ́ Jimoh mò ń ṣọ yín
Ẹ ẹ̀ le mù’gò kan