Títílayọ̀ ọmọ Káyọ̀dé
DCP Operations Lagos State ọkọ Kẹ́mi
(DCP Operations Lagos State ọkọ Kẹ́mi)
Gbajúmọ̀ Gbajúmọ̀ bàbá t’ẹdúnjọbí ọmọ méjì
Owó bàbá Dèjì Dèjì bàbá Ayọ̀bámi o
Bàbá Olúṣọlá, Bàbá t’Àbíkẹ́ Motúnráyọ̀ yìí o ṣé
DCP Operations fún Lagos State ọkọ Kẹ́mi
(DCP Operations fún Lagos State ọkọ Kẹ́mi)
Èèyàn tiwa ni o
Olọ́pàá gidi tó bá ń ṣ’ọ̀rẹ́ ará ìlú
Ó yẹ kí àwọn náà kí wọ́n jó
Ojoojúmọ́ ọjọ́ iṣẹ́, Ojoojúmọ́ ọjọ́ iṣẹ́
Kí Jack má di dull boy
Máa jayé orí ẹ ọkọ Kẹ́mi Kẹ́mi
One more time
DCP Operations ní Lagos State ọkọ Kẹ́mi
(DCP Operations ní Lagos State ọkọ Kẹ́mi)
Abbey ọmọ t’Èjígbádéró
Ó ní kí n bá òun kí gbogbo Royal pioneers truth and love
Olọorì mọ̀délé sister tèmi Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn awo Àbíkẹ́
Awo Alhaja Bukky mi aya Saka ọ̀rẹ́ wa
Ìyá aláṣọ ní Oshodi Saka ọmọ Fọlábí
Awo tèmi Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn
A ti jọ ń bá ara wa bọ̀ ní tipẹ́ tipẹ́
Ọlọ́hun bá mi ṣọ́ ẹ lọ́sàn-án lóru
Gbogbo ohun to tí fojú ọwọ́ ṣe kò ní bàjẹ́
Àánú Ọlọ́hun Ọba Saka kó máa bá ẹ
Saka Igbira Olúayé Fújì mò ń kí ẹ
Ọkọ Bukky baby o o
Alhaja Bukky mi awo ti Mọ́délé
Mọ́délé a kìí l’Ọ́ba ká lójo
Àbíkẹ́ mo ti bèrè níbi
Ah!..
Mo ti bèrè ẹ níbí Àbíkẹ́ adé Fausatu mi ńkọ́?
Àbíkẹ́ ń bẹ nílùú America á bá ire wá sílé
Mọ́délé, Àní a kìí l’Ọ́ba ká lójo
Mo mọ àwọn èèyàn tèmi Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn ọmọ ni ọ́ Ọmọ́délé
Sister tèmi Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn mo kí ẹ Mọ́délé
Ìlérí Olúwa á ṣe mọ́ ẹ lọ́wọ́ lọ́lá Ọlọ́run Ọba
Á ṣẹ mọ́ ẹ lára Èjígbádéró
Ìwọ lo mọ ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn
O mọ bó ti ṣe wù ẹ́
Torí ohun tú ó ń wu ni
Ló ń pọ̀ lọ́lá ẹni ọmọ t’Èjígbádéró
Adura ẹ á máa gbà o
Kòsí ìgbà tí ọlọ́hun ọba kò kí ń gbọ ohun tí a bá ń wí
Bó o ṣọ́ kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́, kòsí bí ò ṣe gbọ́
Kó o pariwo sọ́ kó o ṣọ́ sínú
Ọlọ́hun Ọba tó jẹ́ òun l’arínúróde olùmọ̀ràn-ọkàn ó gbọ́ ohun tó o wí
Brother ló jẹ́ fún Tajudeen ọmọ Èjígbádéró
Àwọn ọmọ Alhaja o ṣé
Ọmọ Ramotallahi Alhaja mi dáadáa
Mọ́délé baby, Abbey àní kí là ń fowó ṣe bí a bá lówó lọ́wọ́
Níṣe là ń fowó rayì náà ni
Tani ẹ̀yin rí tó lówó lọ́wọ́
Tó lóun fẹ́ lọ fi ra àbùkù wá sílé
Olówó ń fowó ra iyì náà ni
Ohun ta bá ṣe láwùjọ ta bá ṣe fún gbogbo ará
A mà ń fowó ra iyì náà ni
Bí a bá dé ojú agbo níwájú onílù tó bá jẹ́ eléré ńlá
Bó jẹ́ olówó wẹ́wẹ́ ni níṣẹ là ń fowó ra iyì náà ni
Èyí to ṣe nínú ẹbí ẹ nílé bàbá ẹ o
Àti ní ilé màmá ẹ bó jẹ́ ní ilé àna o
Bó ṣe láàrin ẹgbẹ́ ẹ Saka, à ń fowó ra iyọì náà ni
Ẹ̀bẹ̀ kan tí kò ń bẹ Ọlọ́hun Ọba fún gbogbo náwó náwó
Ọba má pa kadara wa padà sáburú
Náwó náwó ń fowó rayì náà ni
Èjígbádéró ń fowó rayì tó pọ̀ rẹpẹtẹ
Jọ̀ọ́ o Abíọ́dún mi Abbey (ma jayé orí ẹ)
Yeh! Èjígbádéró Abbey (ma jayé orí ẹ)
Eh!
Màá jayé orí mi o (Arábámbí)
Yi padà!
Abbey Bíọ́dún mi Abbey ko jayé orí ẹ
Ọmọ Èjígbádéró Abbey (ko jayé orí ẹ)
Bukky, aya Saka Igbira, bó wu ọlá Ọlọ́hun o (ko jayé orí ẹ)
Ah Mọ́délé, Ọba ló ró mi láṣọ o (ko jayé orí ẹ)
Ah Mọ́délé baby (Mọ́délé baby)
Ẹ ẹ̀ dẹ̀ sọ̀’lù sí mi lára o (torí Mọ́délé Baby)
Sọ̀’lù sí mi lára o (torí Mọ́délé Baby)
Eléyìí làlùjó best, èyí ni Modern Fújì
Àlùjó Wasiu Arábámbí
Ye! Kúrò níbẹ̀
Ẹ jọ̀ọ́ mummy, Mọ́délé jẹ́ n ríjó ọwọ́ ẹ (Mọ́délé baby)