Aya Ológbùró (Live)-文本歌词

Aya Ológbùró (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Oore t’Ọ́lọ́hun Ọba ṣe o à ló já ṣọ́ pẹ́

(Oore tí bàbá mi ó ṣe o ó já sọ́pẹ́)

Ijó dijó Lateefatu Àìná òrósùn mi

Àìná òrósùn mi Lateefa

Ọmọ Samuel Taiwo Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn Lateefa Àìná o

Ọmọ Àbíkẹ́ mi Zeenatu

Aya shefiu mi Ọlámilékan

Lékan ọmọ Kọ́mọláfẹ́ Shmidat

Mother Ọláyínká, mother Wúràọlá, owó mother Fọlábí

Màmá Michael mi, right mother Mubarak mi, Ọlámipọ̀si

Lateefatu Àìná

Oore t’Ọ́lọ́hun Ọba ṣe o à ló já sọ́pẹ́

(Oore tí bàbá mi ó ṣe o, ó já sọ́pẹ́)

Òun ni gbogbo wa ń pè ní Bọ́lájókòó

Ọ̀rẹ́ tani o? Ọ̀rẹ́ Taofeekah

Ọ̀rẹ́ Àlàkẹ́ Taofeekatu Ọmọ́bọ́lájí

Lateefatu Àìná, Àìná òrósùn mi Lateefa

O kú ilédè bàbá ẹ

Àìná Lateefatu, Bolajoko o káre Àìná o

Oore t’Ọ́lọ́hun Ọba ṣe o à ló já sọ́pẹ́

(Oore tí bàbá mi ó ṣe o, ó já sọ́pẹ́)

Mo mà kí ẹ kí ẹ Àìná òrosùn

Làti o kú ilédè bàbá ẹ

Àìná òrosùn mi ọmọ t’Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn

Ọmọ Samuel Taiwo mi Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn o

Bọ́lájòkó mi Lateefatu o, aya Kọ́mọláfẹ́ mi sweetie Lateefah

Lateefatu mi aya wọn ní’jẹ̀bú igbó o

Bọ́lájokó mi sweetie Lateefah

Oore t’Ọ́lọ́hun Ọba ṣe o à ló já sọ́pẹ́

(Oore tí bàbá mi ó ṣe o, ó já sọ́pẹ́)

Ọmọ Àbíkẹ́ Rísíkìyátù mi

Àbíkẹ́ Adé mi Risika

Màmá Bọ́lá Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn, motger Bíọ́lá Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn, mother t’Ọdún Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn mi

Ẹ kú ilédè bàbá yin

O ṣe sàárà fún bàbá ẹ (sàárà á gbà o)

O ṣe sàárà fún bàbá ẹ (sàárá á gbà o)

O ṣe sàárà fún bàbá ẹ (àdúrà á gbà o)

O ṣe sàárà fún bàbá ẹ (àdúrà á gbà o)

Sàárà ló ń bá òkú, àdúrà ló ń bá òkú

Gbogbo sàárà tí a bá ṣe fún òkú ẹni

A máa bá wọn ní gbèje gbẹ̀jọ o

Àyìndé ní kiyamo níbi tí wọ́n fojú sí

Bọ́lá Baby mi Lateefah

Àlàkẹ́ ni n kí ẹ Taofeekatu o

Làtí aya Kọ́mọláfẹ́

Aya Ọlámilékan ọmọ Kọ́mọláfẹ́

Ọ̀rẹ́ Taofeekatu mi Àlàkẹ́ adé mi Bọ́lájí

Bọ́lájí Taofikatu

Taofikatu mi l’Ólúyọ̀lé ilé

Àlàkẹ́ l’Ókè Ìbàdàn

Taofika, òkè Ìbàdàn ṣá ni ìwọ wà, t’o ti gbé ń pawó ajé

Ọmọ ará ìjámọ̀, ọmọ epo ń pọ́n roro

Ǹlẹ́ ọmọ àjà ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀

Wọ́n ń torí àjà jà, Taofika ní kí í ń ṣe lẹ́yìnkùlé òun àlàkẹ́ Taofika, Àlàkẹ́ Taofikatu mi

Àlàkẹ́,ọ̀rẹ́ Bọ́lá Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn Taofika

Bọ́lá, Taofika ló ní n kí ẹ Àlàkẹ́ o

Bọ́lá, o ṣe ṣáárà fún bàbá ẹ àdúrà á gbà o

(O ṣe ṣáárà fún bàbá ẹ àdúrà á gbà o)

Bí n ṣe ń ki Taofikatu, torí Bọ́lá Bọ́lá

Laya Ológbùró mi mà ń náwó

Oṣé o aya Ológbùró (aya Ológbùró)

Rafiatu máa wo’lẹ̀ (aya Ológbùró)

Rafiatu, aya Bátúndé musifa Ológbùró mi (aya Ológbùró)

Gbogbo ẹ̀yin t’Ìbàdàn a ki yín

Ẹ kú àdúrótì gbogbo ẹbí Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn

Rafiatu máa wo’lẹ̀ (aya Ológbùró)

Aya Musiba ọ̀rẹ́ mi o (aya Ológbùró)

Aya Musiba ọ̀rẹ́ mi o (aya Ológbùró)

Torí Bọ́lá Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn, torí Bíọ́lá Ọ̀rẹ́dẹ̀yìn, torí Ọdún

Rafiatu máa wo’lẹ̀ (aya Ológbùró)

Èèyàn ti Mutia elépo o (aya Ológbùró)

Torí Bọ́lá Bọ́lá aya Kọ́mọláfẹ́