bà Olúayé (Live)-文本歌词

bà Olúayé (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Àyìndé o, Olúayé ibà arábámbí ọkùnrin ogun o

(Àyìndé o Olúayé ibà arábámbí ọkùnrin ogun)

Àyìndé o, Olúayé ibà arábámbí ọkùnrin ogun o

(Àyìndé o Olúayé ibà arábámbí ọkùnrin ogun)

Olóyè Fìjàbí, Akin má a wolẹ̀ má a ràba ọmọ Fìjàbí wa

Òkè Ìbàdàn nílé Olúyọ̀lé Akin, onílẹ̀ Obì ọ̀rẹ́ mi Fìjàbí

Bàbá Olóyè ní àṣà Fìjàbí Akin, onílẹ̀ obì ọ̀rẹ́ mi Fìjàbí

Akáwọnmọ́’lé ògìdán kùnrin ǹlẹ́ o, ògunmọ gìrì gìrì b’ọjà

Akáwọnmọ́’lé ògìdán kùnrin ǹlẹ́ o, ògunmọ gìrì gìrì b’ọjà

Ọ̀rẹ́ Àyìndé atúwọnká níbi wọ́n ń gbé d’áná irọ́

Èèyàn tí ò mọ Ọba ló ń f’Ọba ṣeré Wasiu Àyìndé

Onílẹ̀ obì ọmọ Fìjàbí Akin

Àyìndé o, Olúayé ibà arábámbí ọkùnrin ogun o

(Àyìndé o Olúayé ibà arábámbí ọkùnrin ogun)

Àkànní ọmọ Láígbadé mọ̀láògbe ó Àkànní Adé

Ọ̀bẹ̀bẹ́ ará Ọ̀yọ́, Ọláígbadé mọ̀láòpé

Ilé ò pé l’obìnrin lè ṣawo, ọ̀sẹ̀ dẹ̀ ò pé l’obìnrin wọ̀’gbàlẹ̀

Ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí Àyìndé (Máyégún)

(Ẹ bámi dúpẹ́, ẹ bámi dúpẹ́ oh-eh ará mí, ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí o)

Ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí Àyìndé (Arábámbí)

(Ẹ bámi dúpẹ́, ẹ bámi dúpẹ́ oh-eh ará mí, ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí o)

Ọlásúnkànmí Àyìndé (àgbàakin Adégoróyè mi o)

Lásúnkànmí Àyìndé (àgbàakin Adégoróyè mi o)

Ó sọ Fújì yìí d’ẹ̀rọ̀ (ṣèbí bí ẹrú là bá máa ṣe o)

Ẹ bá mi dúpẹ́ (Ẹ bá mi dúpẹ́ oh - eh ará mi, ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí o)

Olúwa máa ṣọ́ wa, ká má rin àrìn fẹsẹ̀sí o

(Olúwa máa ṣọ́ wa arábámbí, Olúwa máa ṣọ́ wa ká má rìn àrìnfẹsẹ̀sí o)

Agbára kìí fo kòtò o (kí’re dákun má fò wá dá)

À-lágbàrá kìí fo kòtò o (ire dákun má fò wá dá)

Mo ‘lágbàrá kìí fo kòtò o (ire dákun má fò wá dá)

Olúwa máa ṣọ́ wa (Máyégún)

Olúwa máa ṣọ́ wa ká má rìn àrìnfẹsẹ̀sí o)

Agbára kìí fo kòtò o (kí’re dákun má fò wá dá)

À-lágbàrá kìí fo kòtò o (ire dákun má fò wá dá)

Olúwa máa ṣọ́ wa (arábámbí, Olúwa máa ṣọ́ wa ká má rìn àrìnfẹsẹ̀sí o)

Òréré ohun alàgbà ń wò o

Òréré o, òhun làgbà ń wo o, b’ójú bá fara balẹ̀ á rímú

(Òréré òhun làgbà ń wò, òréré o òhun làgbà ń wò o)

(B’ójú bá farabalẹ̀ á rímú)

Wọ̀ kí ìlú mọ̀, mo tún ti dé

(Olórin t’ayé ń gbádùn ẹ̀ o)

(B’ọ́mọdé bá róyin á s’àkàrà nù)

(Mo gbé tàná dànù, mo tún ti dé)

Ọjọ́ ojúmọ́ ni Fújì ń dùn

(Ọlọ́run Ọba ló f’oyin si, ó sì tún f’ayọ̀ si)

Ọjọ́ ojúmọ́ ni Fújì ń dùn

(Ọlọ́run Ọba ló f’oyin si, ó sì tún f’ayọ̀ si)

Àwọn àgbà (ni wọ́n fi ohun tó da sílẹ̀ t’áwa dé bá)

Àwọn àgbà (ni wọ́n fi ohun tó da sílẹ̀ t’áwa dé bá)

K’éré Fújì má bàjẹ́, lọ́wọ́ gbogbo wa ni

Àwọn àgbà (ni wọ́n fi ohun tó da sílẹ̀ t’áwa dé bá)

Àwọn àgbà (ni wọ́n fi ohun tó da sílẹ̀ t’áwa dé bá)

K’éré Fújì má bàjẹ́ lọ́wọ́ gbogbo wa ni

Àsìá mi lókè yìí, ṣèbí Fújì ló kọ o

Àsìá mi lókè yìí, ṣèbí Fújì ló kọ o

Àsìá mi lókè yìí, ṣèbí Fújì ló kọ o

Ó ń fẹ́ lẹ́ lẹ́ lẹ́ (ṣèbí Fújì ló kọ o)

Àsìá mi lókè yìí, (ṣèbí Fújì ló kọ ó)

Afẹ́fẹ́ ò ní fẹ́, kó má ba igi oko

Afẹ́fẹ́ ò ní fẹ́ kó má kangi oko o

Ẹ gbé Fújì yìí gẹ̀gẹ̀ kárí ayé

(Afẹ́fẹ́ ò ní fẹ́, kó má ba igi oko)

(Afẹ́fẹ́ ò ní fẹ́ kó má kangi oko o)

(Ẹ gbé Fújì yìí gẹ̀gẹ̀ kárí ayé)

Iná t’Ólúwa bá dá (kò ṣe é f’omi pa)

Igi t’Ólúwa bá gbìn (ó ṣòro fà tu)

(Bàbá Dammy Aláyìndé Olúọmọ dé)

Odidi ahun ní ó rà o

(Odidi ahun ní ó rà o)